Agba Osika

Agba Osika

“Agbo ejo enikan da ejo…”
Kini owe omo kaaro oojire pe won? “…Agba osika!”

Bibeli awon onigbagbo Kristi ohun na wipe
“Ema si se oju saaju ni idajo,
Ese idajo eni nla ati kekere bakan na
E ma se beru enikeni tori pe ti Olorun ni idajo”

Awon amofin ti orile ede wa ati ilu oyinbo naa wipe
“Audi alteram partem” ni ede Latini
Ti o tumo si wipe “ki agbo ejo apa mejeeji
Ki a ma d’ajo lai gbo lenu enikeni”

Awon elesin Musulumi paapa so wipe
“Ti eniyan meji ba wa ba e fun idajo
Ma se da ejo fun enikini lai gbo ejo enikeji
Lehin ti o gbo awon mejeeji ni o se ma mo bi o se ma d’ajo”

Eko kan na owe ati asa Yoruba, Bibeli awon onigbagbo Kristi
Esin Musulumi pelu ofin orile ede wa ati gbogbo agbaye ko wa
Adajo, agbalagba tabi olori ti o ba da ejo lai gbo lenu apa mejeeji
O fe ki Olorun da ejo ohun gege bi agba osika

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *